1.The Opening

  1. Ní orúkọ Allāhu, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  2. Gbogbo ọpẹ́ ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá
  3. Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run
  4. Olùkápá-ọjọ́-ẹ̀san
  5. Ìwọ nìkan ni à ń jọ́sìn fún. Ọ̀dọ̀ Rẹ nìkan sì ni à ń wá oore sí
  6. Jíjọ́sìn fún Allāhu níkan ṣoṣo àti dídúró ṣinṣin nínú ìjọ́sìn Rẹ̀ ìtúmọ̀ yìí wà bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Āli ‘Imrọ̄n “Fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ sínú ’Islām ọ̀nà tààrà.” Nítorí náà
  7. ọ̀nà àwọn tí O ṣe ìdẹ̀ra fún,yàtọ̀ sí (ọ̀nà) àwọn ẹni-ìbínú (ìyẹn, àwọn yẹhudi) àti (ọ̀nà) àwọn olùṣìnà (ìyẹn, àwọn nasara)