114.Mankind

  1. Sọ pé: "Mo sá di Olúwa àwọn ènìyàn
  2. Ọba àwọn ènìyàn
  3. Ọlọ́hun àwọn ènìyàn
  4. níbi aburú (Èṣù) oníròyíròyí, olùsásẹ́yìn (fún ẹni t’ó bá dárúkọ Allāh)
  5. (Èṣù ni) ẹni tí ó ń kó ròyíròyí sínú àwọn ọkàn ènìyàn
  6. (Èṣù náà) wà nínú àlùjànnú àti ènìyàn