19.Mary

  1. Kāf hā yā ‘aēn sọ̄d. ìyá ‘Īsā ('alaehi-ssọlātu wa-ssalām) Òun l’Ó ṣà á lẹ́ṣà. Tòhun ti bẹ́ẹ̀ náà ìbá tí sọ àwọn òdodo wọ̀nyẹn nípa Mọryam ìyá Jésù. Ṣebí wọ́n kúkú fi ẹnu àbùkù kan Mọryam ẹ̀dá ni àwọn mìíràn tí Allāhu fi sọrí àwọn sūrah ọ̀rọ̀ Rẹ̀. A kúkú rí sūrah Muhammad gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí sūrah Mọryam. Àmọ́ ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó máa sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di olúwa àti olùgbàlà? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ìyá ‘Īsā sọ sūrah l’ó sọ ‘Īsā tàbí ìyá rẹ̀ di ọlọ́hun ọmọ? Tàbí ṣé nítorí pé wọ́n fi orúkọ Mọryam ṣíṣe tí Allāhu (subhānahu wa ta'ālā) ṣe Mọryam ní ẹ̀ṣà ènìyàn àmọ́ tí Allāhu kò ṣe ìyá àti bàbá Ànábì wa bẹ́ẹ̀ tí Allāhu fi sọrí ẹbí Mọryam a kúkú rí sūrah Ƙuraeṣ
  2. (Èyí ni) ìrántí nípa ìkẹ́ tí Olúwa Rẹ ṣe fún ẹrúsìn Rẹ̀, (Ànábì) Zakariyyā
  3. (Rántí) nígbà tí ó pe Olúwa rẹ̀ ní ìpè ìkọ̀kọ̀
  4. Ó sọ pé: "Olúwa mi, dájúdájú eegun ara mi ti lẹ, orí (mi) ti kún fún ewú, èmi kò sì níí pasán nípa bí mo ṣe ń pè Ọ́, Olúwa mi
  5. Àti pé dájúdájú mò ń páyà àwọn ìbátan mi lẹ́yìn (ikú) mi. Ìyàwó mi sì jẹ́ àgàn. Nítorí náà, ta mí lọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Rẹ ọmọ rere kan
  6. (tí) ó máa jogún mi, tí ó sì máa jogún àwọn ẹbí (Ànábì) Ya‘ƙūb. Kí O sì ṣe é ní ẹni tí O yọ́nú sí, Olúwa mi
  7. Zakariyyā, dájúdájú Àwa máa fún ọ ní ìró ìdùnnú (nípa bíbí) ọmọkùnrin kan, orúkọ rẹ̀ ni Yahyā. A ò fún ẹnì kan ní (irú) orúkọ (yìí) rí ṣíwájú (rẹ̀)
  8. Ó sọ pé: "Olúwa mi, báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí ìyàwó mi jẹ́ àgàn, tí mo sì ti di àgbàlagbà gan-an
  9. (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn ni (ó máa rí).” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún Mi. Mó kúkú dá ìwọ náà ṣíwájú (rẹ̀), nígbà tí ìwọ kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan.”
  10. (Zakariyyā) sọ pé: “Olúwa mi, fún mi ní àmì kan.” (Mọlāika) sọ pé: "Àmì rẹ ni pé, o ò níí lè bá ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta, kì í ṣe ti àmódi
  11. Nígbà náà, ó jáde sí àwọn ènìyàn rẹ̀ láti inú ilé ìjọ́sìn. Ó sì tọ́ka sí wọn pé kí wọ́n máa ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́
  12. Yahyā, mú Tírà náà dání dáradára. A sì fún un ní àgbọ́yé ẹ̀sìn láti kékeré
  13. (Ànábì Yahyā jẹ́) ìkẹ́ àti ẹni mímọ́ kan láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó sì jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu)
  14. (Ó tún jẹ́) oníwà rere sí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì. Kò sì jẹ́ ajẹninípá, olùyapa
  15. Àlàáfíà ni fún un ní ọjọ́ tí wọ́n bí i, àti ní ọjọ́ tí ó máa kú àti ní ọjọ́ tí A óò gbé e dìde láàyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)
  16. Sọ ìtàn Mọryam tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. (Rántí) nígbà tí ó yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ sí àyè kan ní ìlà òòrùn
  17. Ó mú gàgá kan (láti fi ara rẹ̀ pamọ́) fún wọn. A sì rán mọlāika Wa sí i. Ó sì fara hàn án ní àwòrán abara pípé
  18. (Mọryam) sọ pé: “Èmi sá di Àjọkẹ́-ayé kúrò lọ́dọ̀ rẹ, tí o bá jẹ́ olùbẹ̀rù (Allāhu).”
  19. (Mọlāika) sọ pé: “Èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ, (Ó rán mi sí ọ) pé kí n̄g fún ọ ní ọmọkùnrin mímọ́ kan.”
  20. Ó sọ pé: "Báwo ni mo ṣe máa ní ọmọ nígbà tí abara kan kò fọwọ́ kàn mí, tí èmi kò sì jẹ́ alágbèrè
  21. (Mọlāika) sọ pé: “Báyẹn l’ó máa rí.” Olúwa rẹ sọ pé: “Ó rọrùn fún mi. Àti pé nítorí kí Á lè ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn ni. Ó sì jẹ́ ìkẹ́ láti ọ̀dọ̀ Wa. Ó tún jẹ́ ọ̀rọ̀ tí A ti parí.”
  22. Nítorí náà, ó lóyún rẹ̀. Ó sì yẹra pẹ̀lú rẹ̀ sí àyè kan t’ó jìnnà
  23. Ìrọbí ọmọ sì mú un wá sí ìdí igi dàbínù. Ó sọ pé: “Háà! Kí n̄g ti kú ṣíwájú èyí, kí n̄g sì ti di ẹni tí wọ́n ti gbàgbé pátápátá.”
  24. Nígbà náà, (mọlāika) pè é láti ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: "Má ṣe banújẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ti ṣe odò kékeré kan sí ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ rẹ
  25. Mi igi dàbínù náà sọ́dọ̀ rẹ, kí dàbínú tútù, tó tó ká jẹ sì máa jábọ́ sílẹ̀ fún ọ
  26. Nítorí náà, jẹ, mu kí ojú rẹ sì tutù. Tí o bá sì rí ẹnì kan nínú abara, sọ fún un pé: "Dájúdájú mo jẹ́jẹ̀ẹ́ ìkẹ́nuró fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, mi ò níí bá ènìyàn kan sọ̀rọ̀ ní òní
  27. Ó sì mú ọmọ náà wá bá àwọn ènìyàn rẹ̀ (ní ẹni tí) ó gbé e dání. Wọ́n sọ pé: "Mọryam, dájúdájú o ti gbé n̄ǹkan aburú ńlá wá
  28. Arábìnrin Hārūn, bàbá rẹ kì í ṣe ènìyàn burúkú. Àti pé ìyá rẹ kì í ṣe alágbèrè
  29. Ó sì tọ́ka sí ọmọ náà. Wọ́n sọ pé: “Báwo ni a ó ṣe bá ẹni t’ó wà lórí ìtẹ́, t’ó jẹ́ ọmọ òpóǹló sọ̀rọ̀?”
  30. (Ọmọ náà) sọ̀rọ̀ pé: "Dájúdájú ẹrú Allāhu ni èmi. (Allāhu) fún mi ni Tírà. Ó sì ṣe mí ní Ànábì. ẹ̀dá tí ó ń bọ̀wọ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun ẹ̀dá tí ó juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ fún ìlànà àti òfin Ọlọ́hun àti ẹ̀dá tí ó ń jọ́sìn fún Ọlọ́hun lábẹ́ ìlànà àti òfin Ọlọ́hun. Ẹ̀dá náà kò sì níí yọ́nú sí ìlànà àti òfin mìíràn t’ó yàtọ̀ sí ti Ọlọ́hun.” Ẹni tí ó bá ń ṣe ìwọ̀nyẹn fún ohun mìíràn tàbí ẹlòmíìràn but with my flesh I am a slave to the law of sin.” Ìtúmọ̀: “Nítorí náà nígbà náà pẹ̀lú ẹ̀mí mi pẹ̀lú ọkàn àti ara wa ni a fi gbà láti wà lábẹ́ òfin Rẹ̀. Ìwọ̀nba àṣìṣe tí a bá sì fi ara ṣe gẹ́gẹ́ bí àdámọ́ ènìyàn ìrònúpìwàdà àti ìtọrọ àforíjìn ní ọ̀dọ̀ Allāhu ni ọ̀nà àbáyọ lórí rẹ̀. Aláforíjìn
  31. Ó ṣe mí ní ẹni ìbùkún ní ibikíbi tí mo bá wà. Ó pa mí láṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ lódiwọ̀n ìgbà tí mo bá wà nípò alààyè (lórí ilẹ̀ ayé)
  32. (Ó ṣe mí ní) oníwà rere sí ìyá mi. Kò sì ṣe mí ní ajẹninípá, olórí burúkú
  33. Àlàáfíà ni fún mi ní ọjọ́ tí wọ́n bí mi, àti ní ọjọ́ tí mo máa kú àti ní ọjọ́ tí Wọ́n á gbé mi dìde ní alààyè (ní Ọjọ́ Àjíǹde)
  34. Ìyẹn ni (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam. (Èyí jẹ́) ọ̀rọ̀ òdodo tí àwọn (yẹhudi àti nasara) ń ṣeyèméjì nípa rẹ̀
  35. Kò yẹ fún Allāhu láti sọ ẹnì kan kan di ọmọ. Mímọ́ ni fún Un. Nígbà tí Ó bá pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: "Jẹ́ bẹ́ẹ̀." Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀
  36. Àti pé dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà
  37. Àwọn ìjọ (yẹhudi àti nasara) sì yapa ẹnu (sí èyí) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ (ní àsìkò) ìjẹ́rìí gban̄gba lọ́jọ́ ńlá (Ọjọ́ Àjíǹde)
  38. Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa! Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ náà ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé
  39. Ṣèkìlọ̀ ọjọ́ àbámọ̀ fún wọn nígbà tí A bá parí ọ̀rọ̀, (pé kò níí sí ikú mọ́, àmọ́) wọ́n wà nínú ìgbàgbéra báyìí ná, wọn kò sì gbàgbọ́
  40. Dájúdájú Àwa l’A máa jogún ilẹ̀ àti àwọn t’ó ń bẹ lórí rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Wa sì ni wọn yóò da yín padà sí
  41. Mú (ìtàn) ’Ibrọ̄hīm wá sí ìrántí (bí ó ṣe) wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì
  42. Rántí nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé: "Bàbá mi, nítorí kí ni o fi ń jọ́sìn fún ohun tí kò gbọ́rọ̀, tí kò ríran, tí kò sì lè rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ kan kan
  43. Bàbá mi, dájúdájú ìmọ̀ tí ìwọ kò ní ti dé bá mi. Nítorí náà, tẹ̀lé mi, kí n̄g fi ọ̀nà tààrà mọ̀ ọ́
  44. Bàbá mi, má ṣe bọ Èṣù. Dájúdájú Èṣù jẹ́ olùyapa àṣẹ Àjọkẹ́-ayé
  45. Bàbá mi, dájúdájú èmi ń páyà pé kí ìyà kan láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé má fọwọ́ bà ọ́ nítorí kí ìwọ má baà di ọ̀rẹ́ Èṣù (nínú Iná)
  46. (Bàbá rẹ̀) wí pé: “Ṣé ìwọ yóò kọ àwọn ọlọ́hun mi sílẹ̀ ni, ’Ibrọ̄hīm? Dájúdájú tí o ò bá jáwọ́ (nínú ohun tí ò ń sọ), dájúdájú mo máa lẹ̀ ọ́ lókò pa. Tíẹ̀ yẹra fún mi wọ́ọ́rọ́wọ́ ná.”
  47. (’Ibrọ̄hīm) sọ pé: "Àlàáfíà kí ó máa bá ọ. Mo máa bá ọ tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Olúwa mi. Dájúdájú Ó jẹ́ Olóore mi
  48. Àti pé mo máa yẹra fún ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Èmi yó sì máa pe Olúwa mi. Ó sì súnmọ́ pé èmi kò níí pasán pẹ̀lú àdúà mi sí Olúwa mi
  49. Nígbà tí ó yẹra fún àwọn àti n̄ǹkan tí wọ́n ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, A sì ta á lọ́rẹ (ọmọ), ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (ọmọọmọ). A sì ṣe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní Ànábì
  50. Àti pé A ta wọ́n lọ́rẹ láti inú ìkẹ́ Wa. A sì ní kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ wọn ní dáadáa
  51. Sọ ìtàn (Ànábì) Mūsā tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ ẹni-ẹ̀ṣà, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì
  52. A pè é ní ẹ̀bá àpáta ní apá ọwọ́ ọ̀tún (Mūsā). A sì mú un súnmọ́ tòsí láti bá a sọ̀rọ̀
  53. Láti inú ìkẹ́ Wa A sì fi arákùnrin rẹ̀, Hārūn, (tí ó jẹ́) Ànábì, ta á lọ́rẹ
  54. Sọ ìtàn (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olùmú-àdéhùn-ṣẹ, ó jẹ́ Òjíṣẹ́, (ó tún jẹ́) Ànábì
  55. Ó máa ń pa ará ilé rẹ̀ ní àṣẹ ìrun kíkí àti Zakāh yíyọ. Ó sì jẹ́ ẹni ìyọ́nú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀
  56. Sọ ìtàn (Ànábì) ’Idrīs tí ó wà nínú al-Ƙur’ān. Dájúdájú ó jẹ́ olódodo pọ́nńbélé, (ó sì jẹ́) Ànábì
  57. A sì gbé e sí àyè gíga (nínú sánmọ̀)
  58. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣe ìdẹ̀ra fún nínú àwọn Ànábì, nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) Ādam àti nínú àwọn tí A gbé gun ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú (Ànábì) Nūh àti nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Isrọ̄’īl àti nínú àwọn tí A ti fi mọ̀nà, tí A sì ṣà lẹ́ṣà. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Àjọkẹ́-ayé fún wọn, wọ́n máa dojú bolẹ̀; tí wọ́n á foríkanlẹ̀, tí wọ́n á sì máa sunkún
  59. Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn, tí wọ́n rá ìrun kíkí láre, tí wọ́n tẹ̀lé àwọn yòdòyìndìn ẹ̀mí. Láìpẹ́ wọn máa pàdé ìparun (nínú Iná)
  60. Àyàfi ẹni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn wọ̀nyẹn ni wọn yóò wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. A ò sì níí ṣàbòsí kan kan sí wọn
  61. (Wọn yóò wọ inú) àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn sí ìpamọ́ fún àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Dájúdájú (Allāhu), àdéhùn Rẹ̀ ń bọ̀ wá ṣẹ
  62. Wọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀ àfi àlàáfíà. Ìjẹ-ìmu wọn wà nínú rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́
  63. Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A óò jogún rẹ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù (Mi) nínú àwọn ẹrúsìn Wa
  64. Àwa (mọlāika) kì í sọ̀kalẹ̀ àyàfi pẹ̀lú àṣẹ Olúwa rẹ. TiRẹ̀ ni ohun tí ń bẹ níwájú wa, ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wa àti ohun tí ń bẹ láààrin (méjèèjì) yìí. Olúwa rẹ kì í sì ṣe onígbàgbé
  65. Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohun tí ń bẹ láààrin àwọn méjèèjì. Nítorí náà, jọ́sìn fún Un, kí ó sì ṣe sùúrù lórí ìjọ́sìn Rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ó tún ń jẹ́ orúkọ Rẹ̀
  66. Ènìyàn ń wí pé: “Ṣé nígbà tí mo bá kú, Wọn yóò tún mú mi jáde láìpẹ́ ní alààyè?”
  67. Ṣé ènìyàn kò rántí pé dájúdájú Àwa ni A ṣẹ̀dá rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nígbà tí kò tí ì jẹ́ n̄ǹkan kan
  68. Nítorí náà, mo fi Olúwa rẹ búra; dájúdájú A máa kó àwọn àti àwọn èṣù jọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú wọn wá sí ayíká iná Jahanamọ lórí ìkúnlẹ̀
  69. Lẹ́yìn náà, dájúdájú A máa mú jáde nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan èyíkéyìí nínú wọn tí ó le jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ dídá sí Àjọkẹ́-ayé
  70. Lẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa nímọ̀ jùlọ nípa àwọn t’ó lẹ́tọ̀ọ́ sí wíwọ inú Iná
  71. Kò sí ẹnì kan nínú yín àfi kí ó débẹ̀. Ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ dandan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ. 74:30-31. Bákan náà, kalmọh “wārid” t’ó jẹyọ nínú āyah 71 jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ tí wọ́n ṣẹ̀dá láti ara ọ̀rọ̀-ìṣe “warada”. Nínú al-Ƙur’ān, ìtúmọ̀ méjì péré l’ó wà fún “warada”. “Warada” túmọ̀ sí “ó dé sí ibi tí kiní kan wà, ó sì wọ inú n̄ǹkan náà”, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ yìí ṣe wà nínú sūrah Hūd 11:98 àti sūrah al-’Anbiyā’
  72. igun kìíní kejì máa wá lábẹ́ àkórìn àwọn mọlāika kan ni. Ìyẹn ni pé àwọn mọlāika kan l’ó máa kó gbogbo ẹ̀dá lọ sórí afárá Iná nítorí pé
  73. Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa t’ó yanjú fún wọn, àwọn t’ó ṣàì gbàgbọ́ yóò sọ fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo pé: “Èwo nínú ìjọ méjèèjì (àwa tàbí ẹ̀yin) l’ó lóore jùlọ ní ibùgbé, l’ó sì dára jùlọ ní ìjókòó?”
  74. Àti pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn, tí wọ́n dára jùlọ ní ọrọ̀ (ayé) àti ní ìrísí
  75. Sọ pé: “Ẹni tí ó bá wà nínú ìṣìnà, Àjọkẹ́-ayé yó sì fẹ (ìṣìnà) lójú fún un tààrà, títí di ìgbà tí wọn máa rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àdéhùn fún wọn, yálà ìyà tàbí Àkókò náà. Nígbà náà, wọn yóò mọ ẹni tí ó burú jùlọ ní ipò, tí ó sì lẹ jùlọ ní ọmọ ogun
  76. Allāhu yó sì ṣàlékún ìmọ̀nà fún àwọn t’ó mọ̀nà. Àwọn iṣẹ́ rere ẹlẹ́san gbére lóore jùlọ ní ẹ̀san, ó sì lóore jùlọ ní ibùdésí lọ́dọ̀ Olúwa rẹ
  77. Sọ fún mi nípa ẹni t’ó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí ó sì wí pé: “Dájúdájú wọn yóò fún mi ní dúkìá àti ọmọ!”
  78. Ṣé ó rí ìkọ̀kọ̀ ni tàbí ó rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé
  79. Rárá. A máa ṣàkọsílẹ̀ ohun t’ó ń wí. A sì máa fẹ ìyà lójú fún un tààrà
  80. A ó sì jogún ohun t’ó ń wí fún un. Ó sì máa wá bá Wa ní òun nìkan
  81. Wọ́n sọ àwọn kan di ọlọ́hun lẹ́yìn Allāhu nítorí kí wọ́n lè fún wọn ní agbára
  82. Rárá. Wọ́n máa tako ìjọ́sìn wọn, wọ́n si máa di ọ̀tá wọn
  83. Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Àwa ń rán àwọn èṣù sí àwọn aláìgbàgbọ́ ni, tí wọ́n sì ń tì wọ́n ní ìtìkutì (síbi ẹ̀ṣẹ̀)
  84. Nítorí náà, má ṣe kánjú nípa (ìyà) wọn. A kúkú ń ka (ọjọ́) fún wọn ní kíkà tààrà
  85. (Rántí) ọjọ́ tí A óò kó àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) jọ sọ́dọ̀ Àjọkẹ́-ayé lórí n̄ǹkan ìgùn
  86. A sì máa da àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ sínú iná Jahanamọ wìtìwìtì
  87. Wọn kò níí ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gba àdéhùn láti ọ̀dọ̀ Àjọkẹ́-ayé
  88. Wọ́n wí pé: "Àjọkẹ́-ayé fi ẹnì kan ṣe ọmọ
  89. Dájúdájú ẹ ti mú n̄ǹkan aburú wá
  90. Àwọn sánmọ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nítorí rẹ̀, ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àwọn àpáta sì fẹ́rẹ̀ dà wó lulẹ̀ gbì
  91. fún wí pé wọ́n pe ẹnì kan ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé
  92. Kò sì yẹ fún Àjọkẹ́-ayé láti fi ẹnì kan ṣe ọmọ
  93. Kò sí ẹnì kan nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àyàfi kí ó wá bá Àjọkẹ́-ayé ní ipò ẹrúsìn
  94. Dájúdájú (Allāhu) mọ̀ wọ́n. Ó sì ka òǹkà wọn tààrà
  95. Gbogbo wọn yó sì wá bá A ní Ọjọ́ Àjíǹde ní ìkọ̀ọ̀kan
  96. Dájúdájú àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, Àjọkẹ́-ayé yóò fi ìfẹ́ sáààrin wọn
  97. Nítorí náà, A kúkú ṣe kíké al-Ƙur’ān ní ìrọ̀rùn (fún ọ) pẹ̀lú èdè abínibí rẹ nítorí kí o lè fi ṣe ìró ìdùnnú fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu) àti nítorí kí o lè fi ṣe ìkìlọ̀ fún ìjọ oníyàn-jíjà
  98. Mélòó mélòó nínú ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn! Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró ẹnì kan kan nínú wọn mọ́ tàbí (ǹjẹ́) o gbọ́ ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ wọn bí